This translation is incomplete. Please help translate this article from English.

Àròkọ yíì ṣàpèjúwe irúfẹ́ àgbékalẹ̀ àwọn àmúyẹ tí ìṣàfilọlẹ̀ gbọ́dọ̀ ní láti lè pín ní Firefox Marketplace. Àwọn àmúyẹ wọ̀nyí ni a sàgbékalẹ̀ láti jẹ́ gbèndéke fún ìwúlò àwọn olùmúgbèrú àti àwọn olùṣàmúlò àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ láti Firefox Marketplace. Àwọn olùmúgbèrú fẹ́ ìrọ̀rùn, ṣí ṣẹ̀ntẹ̀lé, àti àmúyẹ tí kò lé tì wọ́n lè gbọ́kànlé láti kọ́ iṣẹ́ wọn lé. Ní ọ̀nà míìràn, àwọn olùsàmúlò fẹ́ ìdànilojú pé àwọn ìṣàfilọlẹ̀ ní ààbò, yóò ṣiṣẹ́ lóri ohun elò wọn àtipé ìṣàfilọ́lẹ̀ yóò ṣe ohun tí ó ní yóòṣe. Àwọn àmúyẹ ìṣàfilọ́lẹ̀ ìṣàlẹ̀ ni lọ́kàn ṣe gbèndéke láàrín àwọn ìní.

Èyí ni àwọn èròǹgbà Mozilla fún ohun tí àgbéyẹ̀wò ìṣàfilọ́lẹ̀ jẹ́ àti tí kòjẹ́:

 • Àmúyẹ ní a ó lò ní dídára díẹ̀, ìlàànù, àti ní ọ̀nà ṣíṣẹ̀ntẹ̀lé. Ìlànà àyẹ̀wò ìṣàfilọ́lẹ̀ ni a kò pinnu láti jẹ́ olùṣóbodè, ṣùgbọ́n ipò ìfọwọ́bà tí a fẹ̀hìntì tí ó pèsè ìjábọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún olùmúgbèrú láti ṣe àṣẹyọrí.
 • Olùṣàtúntò kìíṣe àjọṣe QA! Ní àkókò ìlànà àyẹ̀wò, ẹnìkan yóò wo ìfarahàn ìṣàfilọ́lẹ̀ yóò sì lo ìṣẹjú díẹ̀ láti lo ohun elò gẹ́gẹ́bí olùṣàmúlò déédée ́yóò ti ṣe.
 • Bí ìṣàfilọ́lẹ̀ àyẹ̀wò ìṣàfilọ́lẹ̀ bá kùnà, olùṣàtúntò ni a ó fúnní àlàyé tó yèkoro nípa ìṣòro tí a rí, àwọn ìgbésè láti ṣàtúnpèsè, àti ní tó ṣééṣe, olùṣàtúntò yóò tọ́ka olùmúgbèrú sí ọnà tótọ́ nípa ìpèsè àwọn ìsopọ̀ sí àwọn ìkìlẹ́hìn ìlànà ìṣàmúlò tótọ́ tàbí ṣe ìgbàníyànjú lóri àwọn ìyípadà tí ó yẹ láti ṣe.  
 • Àwọn olùṣàtúntò kìíṣe ìdajọ́ bíi ìṣàfilọ́lẹ̀ yóòṣerí, àyàfi bíi ìṣàfilọ́lẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ìṣàfilọ́lẹ̀ ìpínfọ̀ tí àyọkà àwọ̀ pupa lóri ìpínlẹ̀ oròm̀bó ni akòní kọ̀ nítorí ó bùrẹ́wà, ṣùgbọ́n yóò di kíkọ̀ bí kòbáṣe kàá.
 • A sábà maá ń fún olùmúgbèrú ní ànfààní ìdanilojú. Bí kòbasí ìdanilójú bóyá kí a kọ ìsàfilọ́lẹ̀, àwọn olùṣàtúntò yóòṣe àwọn ìbéèrèṣáajú ṣíṣe ìkọ̀sílẹ̀. A kòní dédé (mọ̀ọ́mọ̀) kọ ìṣàfilọ́lẹ̀ nítorí ìṣòro pẹpẹ tí kòsí ní abẹ́ ìṣàkóso olùmúgbèrú; ṣùgbọ́n alè dá ìgbàwọlé dúró bí a kòbálè mú ìṣàfilólẹ̀ ṣiṣẹ́.

Security Aabo

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé ti ààbò ayàwòrán ìṣàfilọ́lẹ̀ ni o wà níbí: https://wiki.mozilla.org/Apps/Security

 • Àfihàn ìṣàfilọ́lẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ pín láti orísun kánnà bíi ti ìṣàfilọ́lẹ̀.
 • Àfihàn ìṣàfilọ́lẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ pín Akọ́ọ̀lè Irúfẹ́-Akóònú ti ohun elò/ x-web-app-manifest+json.
 • Ìṣàfilọ́lẹ̀ kò gbọdọ̀ lo àyípadà tàbí iframes láti gbàwálẹ̀ akóònù ti a kò fún olùmúgbèrú láṣẹ láti lò.
 • Àwọn àṣẹ ìbéèrè ni a gbọ́dọ̀ ṣàlàyé nínu ìṣàfihàn ìṣàfilọ́lẹ̀ pẹ̀lú àpèjúwe èrèdí ìbéèrè fun.
 • Ànfààní type àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ yóò la àwọn àyẹwò kan kọjá, pẹ̀lú àpèjúwe kóòdù, nítorí ohun iṣẹ́ àìtọ́ àti àdánù dátà olùṣàmúlò pẹ̀lú ànfààní APIs.
 • Ìlànà-Ààbò-Akóònú (CSP) náà tí a túnmọ̀ nínu ìṣafihàn ìṣàfilọ́lẹ̀ pinnu ohun tí kóòdù ìṣàfilọ́lẹ̀ lèṣe. Àkùnàyàn náà, bíkòṣe ṣepàtó, fún àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ tí kòní ànfaaní ní ó jẹ́ irúkan pẹ̀lú ojú wẹ́ẹ̀bù; àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ type ànfaaní ni restrictive default. Ìjábọ̀ ìjẹ́rì tí a ṣẹ̀dá ní ìfilọ́lẹ̀ ní Firefox Marketplace yóò ṣàfihàn ìrúfin alágbára CSP nínu ìṣàfilọ́lẹ̀ rẹ̀ - ṣùgbọ́n ṣọ́ra fún irọ́-àìtọ́ àti ìlò ní àwọn apákan ti àwọn ibi-ìpamọ́ ẹnìkẹ́ta tí o kò lò.

Ìpamọ́

 • Olùmúgbèrú gbọ́dò so ìlànà ìpamọ́ pọ̀ lákòkò ìfàkalẹ̀, ṣùgbọ́n kòsí àwọn àmúyẹ fún fọ́màtì àti àkóónú ti ìlànà ìpamọ́ yíì. Wà lómìníra láti lo privacy policy template wa. Bákanná, wo àwọn privacy policy guidelines wa.  

Àkóónú

 • Ìṣàfilọ́lẹ̀ yóòwù tí ó kúnà àwọn Ìtọsọ́nà Àkóónú wa nísàlẹ̀ ni a kò gbà. Bí o báròpé o ní ànfààní ẹjọ́, jọ̀wọ́ bèèrè lówọ olùṣàtúntò fún àlààyé, bí ìṣàfilọ́lẹ̀ kò bàìtí ṣetán láti fàsílẹ̀. A fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wà lójúpò, ju kí o lo àkókò púpọ̀ lóri àkoonú tí a o kọ̀.
 • Bíbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ní Ṣẹ̀rẹ̀ 2014, gbogbo àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ gbọ́dọ̀ gba ìgbéléwọ̀n láti ọ̀dọ̀ Àgbájọpọ̀ Ìgbéléwọ̀n Gbogboogbò Ọjọ́ Orí (IARC). Láti gba ìgbéléwọ̀n, a ó darí rẹ síbi ìbéèrè díẹ̀ lákókò ìlànà ìfisílẹ̀, wá sì gba ìgbéléwọ̀n kíákíá. Ìwifún si nípa ìlànà ìgbéléwọ̀n wà here.
 • Yíyà aṣàfihàn àti àwọn àpèjúwe tí a fàsílẹ̀ fún Firefox Marketplace gbọ́dọ̀ ṣoojú ìṣàfilọ́lẹ̀ dáradára. Ó lè ṣàfikún "ìtajà" àwọn àwòrán 1-2 tí o ṣàfihàn ìbámu, ṣàfiwé àwọn àwọn àbùdá, tàbí lọ́nà míìràn iṣẹ̀dásílẹ̀ èrè, ṣùgbọ́n ó kérè yíya àsàfihàn ìṣàfilọ́lẹ̀ kan gbọ́dọ̀ wà lóju iṣẹ́, kí àwọn olùṣàmúlò léṣe àkọ́wọ̀ ohun tí wọ́n ń rígbà. Bí ọ̀kan nínu yíyà àṣàfihàn rẹ bájẹ́ àṣàfihàn ìfọ́nsí tàbí ṣàfilọ́lẹ̀, o gbọ́dọ̀ ṣàfikún yíyà àṣàfihàn ti ipá iṣẹ́ ti ohun elò rẹ  
 • Nínu ìfàrahàn ìṣàfilọ́lẹ̀, àwọn locale keys gbódọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìsọdìbílẹ̀ ti ìsàfilọ́lẹ̀ rẹ̀ kín lẹ́hìn. Nípa ìpèsè kọ́kọ́rọ́ tìbílẹ̀ ní Polish, olùṣàmúlò yóò lérò ìṣàfilọ́lẹ̀ rẹ̀ láti wà lójú iṣẹ́ ní èdè náà.
 • Àwòrán aṣàmì ìṣàfilọ́lẹ̀ gbọ́dọ̀ tẹ̀lé Firefox OS app icons style guide.  Àwòrán aṣàmì 128 x 128 nìkan ni dandan, ṣùgbọ́n a tún gbàniyànjú àwòrán aṣàmì 512 x 512 pẹ̀lú (fún àwọn àlàyé si, wo Icon implementation for apps.) Kíyèsi pé àwòrán aṣàmì lè roboto, roboto onígun mẹ́rin, tàbí onígun mẹ́rin, gẹ́gẹ́bí ìlànà àrà.    

Ìtọ́sọ́nà àkóónú

Àtòkọ yíi ṣàlàyé àwọn irufẹ́ àkóónú tí ó yẹ fún Firefox Marketplace. Àtòkọ yíi jẹ́ àlalàyé, kìíṣe onítunmọ̀, asìle ṣe àfikún rẹ̀. Bí a bá rí ohun elò ní ọ̀nà àìtọ́ nínu ìtọsọ́nà àkóónú yìí, Mozilla ní ẹ̀tọ́ láti ṣàyọkúrò ohun elò kíákíá ní Firefox Marketplace.

 • Kòsí ohun èlò iṣẹ́ ìfẹkúfẹ̀ ìhòhò, tàbí ìtọkasí ajẹmáwòrán ìhòhò ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí jàgídìjàgan.
 • Kòsí àkóónú tó lòdì sí àwọn ẹ̀tọ̀, pẹ̀lú ohun ìní ọlọgbọ́n tàbí ẹ̀tọ́ àdáni tàbí ẹ̀tọ́ ìkọ̀kọ̀ tàbí ìṣàfihàn gbogbo ènìyàn.
 • Kòsí àkóónú tí a gbékalẹ̀ láti ṣe ìjàm̀bá fún Mozilla tàbí àwọn olùṣàmúlò (bíi àwọn kóòdù aṣèjàǹbá, àkóràn, sípáíwíà tàbí aṣejànbá).
 • Kòsí àkóónú tí ó jẹ́ aláìbófomu tàbí ṣèmúgbòòrò àwọn ìwà aláìbófomu.
 • Kòsí àkóónú tí o ń tani, ṣini lọ́nà, jẹ́ jìbìtì tàbí tí a gbékalẹ̀ láti wọlé láìgba ẹ̀tọ́ tàbí ṣe àwọn iṣẹ́ míìràn láti jí ìdámọ̀ ẹni.
 • Kòsí àkóónú tí ó ṣe ìpolowó tẹ́tẹ́.
 • Kòsí àkóónú tí o ńṣe ìpòlòngo tàbí ṣe ìṣakoso àwọn ọjà tàbí iṣẹ́ tí kò tọ́.
 • Kòsí àkóónú tí o ńṣe alọ́ni nọ́wọ́gbà awọn ọmọde.
 • Kòsí àkóónú tí ó ń wọ́ni nílẹ̀, dúnkòkò mọ́ni, ńfa ìwà jàgídìjàgan, tàbí fàyegbà ìwà ìpàlára tí ó lòdì sí ènìyàn tàbí tí ó dá lórí ẹgbẹ́ ọjọ́ orí, obí tàbí akọ, ẹ̀yà, ìlú, ìpínlẹ̀ ìlú, ẹ̀sìn, òye ìbánilopọ̀, àìlera, ẹ̀sìn, ibi ìtẹ̀dó tàbí àwọn ẹgbẹ́ ìdábòbò tàbí tí ó ṣòkunfa ìkórira ọ̀rọ̀.
 • Kòsí àkóónú tí ó ṣi olùṣàmúlò lọ́nà nípa ṣíṣe ìpìnnu rírà.

Ìṣiṣẹ́sí

 • Olùṣàtúntò gbọ́dọ̀ le ṣojúṣe àwọn àbùdá ìpòlòngo gan ti ìṣàfilọ́lẹ̀. Àṣìṣe ẹwà ara àti àìrójú kékèké ni a ó fisùn fún olùmúgbèrú, ṣùgbọ́n kòní dẹ́kun ìṣàfilọ́lẹ̀ tí a fọwọ́sí.
 • Ìṣàfilọ́lẹ̀ kò gbọ̀dọ̀ gbọ̀jẹ̀gẹ́ ìṣiṣẹ́ ohun elò tàbí ìfẹ̀sẹ̀múlẹ̀.

Lílò

 • Olùmúgbèrú gódọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tí ó ní ìtunmọ̀ láti ṣọ́lọ̀ ètò-ìrísí ìṣàfilọ́lẹ̀ fún pẹpẹ tí a dojúsọ. Ìwúlò àmuyẹ yíì ní láti mọ́ àwọn ìjákulẹ̀, bíi:
  • Ìṣàfilọ́lẹ̀ tí a fàkalẹ̀ fún alágbèká tí o sì jẹ́ ojú-òpó-wẹ́ẹ̀bù àtẹ iṣẹ́.
  • Ìṣàfilọ́lẹ̀ tí o fihàn pé kòtó láti kún alàfo àṣàfihàn (ro ìṣàfilọ́lẹ̀ 320x480 tí ó kàn ńgba ààyè kọ̀rọ̀ òkè lórí kọ̀ǹpútà alogègé, tí àwọn àṣàfihàn yóòkú di òfìfo. Èyí ni a kò pinnu!)
 • Ìṣàfilọ́lẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣàmúlò ọ̀nà ìyíkíri tirẹ̀ kí o sì má gbẹ́kẹ́lè aṣàwákiri kúrómù fún bọ́tínì ẹ̀yìn aṣeémú, èyí tí kòní sí lórí ohun elò.
  • Fún àpẹẹrẹ, ìṣàfilọ́lẹ̀ ni a ó kò bí olùṣàtúntò bá yílọ ìbòmíràn láarín ìṣàfilọ́lẹ̀ tí kòsí lè yípadà. Ìṣàfilọ́lẹ̀ KÓ nílò láti ṣàmúlò bọ́tìnì pẹpẹ tí ó wọ́pọ̀ sí àwọn ìṣàfilọ́lẹ̀ ìbílẹ̀.
  • Ní Firefox OS v1.1 àti ju bẹ́ẹ̀lọ, o lè ṣàfikún ìfàrahàn àbùdá chrome láti ṣàfikún ìṣàkóso ìyíkíri kékeré.
 • Ìdá-ìpìlẹ̀ ìyíkiri, gẹ́gẹ́bí bọ́tìnì àwọn ìsopọ̀, gbọ́dọ̀ rọrùn láti ṣíra tẹ tàbí fọwọ́ba.

Ìlànà ÀtòkọÌtìpa

A lérò pé a kòní lò, ṣùgbọ́n a ní ẹ̀tọ́ láti yọkúrò ("àtòkọtítì") ìṣàfilọ́lẹ̀ tí a tẹ̀ jádè tí a wá rí nígbòyá láti rúfin ààbò, ìpamọ́, tàbí àmúyẹ àkóónú, tàbí ìṣàfilọ́lẹ̀ tí ó ń bá ìlànà ètò jẹ́ tàbí ìṣesì nẹ́tíwọkì. Àwọn olùmúgbèrú ni a sọ fún ipò ohun ṣáajú kí a tó dẹ́bù ìṣàfilọ́lẹ̀, a ó ròpé ó jẹ́ ọmọ ìlú rere àyàfi bí a bání ẹ̀rí míìrán, yóòsì gba ìrànwọ́ kíkún láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣàtúntò ìsàfilọ́lẹ̀ láti sọ ohun tí o ńlọ kí wọ́n sì yanjú ìṣòro náà. Àwọn àpẹẹrẹ tí ó tọ́ ní ipò níbi àtòkọtítípa tí a fọwọsí ni:

 • Ìwọlé ohun elò láìtọ́
 • Ìwé àìbèèrèfún
 • Yíyí àkóónú padà láti Àwọn Àwòrán Púúpì v1.0 sí Ìwà ipá jàgídìjàgan v1.0 (láti ṣàtúntò ìmúgbòòrò àkóónú)
 • Ìwà àìtọ́ tólè ti ìṣàfilólẹ̀ fún ìdá ọgórùn àwọn olùṣàmúlò ńlá — ìmúwálẹ̀ iṣẹ́ fóònù, fífi ìtúntàn, fífa ìpàdánù dátà olùṣàmúlò, abbl. Níbití àwọn olùṣàmúlò kòlèsọ ìdí pàtó bóyá ìṣàfilọ́lẹ̀ ni àti ibití wọ́n kòìtí tan ìṣòro ìtúntàn ohun elo náà.
 • Ìlo ìṣàfilólẹ̀  láti ṣe ìdòjúkọ lóri nẹ́tíwọkì, bíi pínpín ìkọ iṣẹ́ (DDOS).

Ìwifún si

Àwọn ohun èlò wọ̀nyí pèsè ìwifún si lóri ìlànà àgbéyẹ̀wò àti àwọn ìṣàfilólẹ̀ olùṣàmúlò:

 • Reveiwers test criteria — ojú ewé yíì ṣàlàyé pé ìdánwò ti ìṣàfilólẹ̀ olùṣàmúlò yóòṣe lórí àwọn ìṣàfilólẹ̀
 • App reviewers — bí a ó ṣe kànsi ẹgbẹ́ ìṣàfilólẹ̀ amúgbèrú àti ìkópa àwọn ìṣàfilólẹ̀ àmúgbèrú

Document Tags and Contributors

Contributors to this page: DevonB
Last updated by: DevonB,